2 Kronika 20:5
2 Chronicles 20:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun.
2 Chronicles 20:5 in English
2 Chronicles 20:5 · Berean Standard Bible
Then Jehoshaphat stood in the assembly of Judah and Jerusalem in the house of the LORD in front of the new courtyard
Context
3Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. 4Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a. 5Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. 6O sì wí pé,
“Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú. 7Ìwọ ha kọ́ Ọlọ́run wa, tí o ti lé àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí jáde níwájú àwọn ènìyàn Israẹli, tí o sì fi fún irú-ọmọ Abrahamu ọ̀rẹ́ rẹ láéláé?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.