2 Kronika 20:4
2 Chronicles 20:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a.
2 Chronicles 20:4 in English
2 Chronicles 20:4 · Berean Standard Bible
So the people of Judah gathered to seek the LORD, and indeed, they came from all the cities of Judah to seek Him.
Context
2Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jehoṣafati, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá bá ọ láti apá kejì Òkun láti Siria. Ó ti wà ní Hasason Tamari náà” (èyí tí í ṣe En-Gedi). 3Nípa ìró ìdágìrì, Jehoṣafati pinnu láti wádìí lọ́wọ́ Olúwa, ó sì kéde àwẹ̀ kíákíá fún gbogbo Juda. 4Àwọn ènìyàn Juda sì kó ara wọn jọ pọ̀ láti wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa; pẹ̀lúpẹ̀lú, wọ́n wá láti gbogbo ìlú ní Juda láti wá a. 5Nígbà náà Jehoṣafati dìde dúró níwájú àpéjọ Juda àti Jerusalẹmu ní ilé Olúwa níwájú àgbàlá tuntun. 6O sì wí pé,
“Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóso lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.