2 Kronika 2:10
2 Chronicles 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.”
2 Chronicles 2:10 in English
2 Chronicles 2:10 · Berean Standard Bible
I will pay your servants, the woodcutters, 20,000 cors of ground wheat,* 20,000 cors of barley,* 20,000 baths of wine,* and 20,000 baths of olive oil.*”
Context
8“Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ. 9Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀. 10Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.” 11Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni:
“Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.” 12Hiramu fi kún un pe,
“Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.