2 Kronika 18:1
2 Chronicles 18:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀.
2 Chronicles 18:1 in English
2 Chronicles 18:1 · Berean Standard Bible
Now Jehoshaphat had riches and honor in abundance, and he allied himself with Ahab by marriage.
Context
1Nísinsin yìí Jehoṣafati sì ní ọrọ̀ àti ọlá púpọ̀, ó sì dá àna pẹ̀lú Ahabu nípa fífẹ́ ọmọ rẹ̀. 2Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá Ahabu lálejò ní Samaria. Ahabu sì pa àgùntàn àti màlúù púpọ̀ fún àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ó sì rọ̀ ọ́ láti dojú ìjà kọ Ramoti Gileadi. 3Ahabu ọba Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jehoṣafati, ọba Juda pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Ramoti Gileadi?”
Jehoṣafati sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ nínú ogun náà”.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.