2 Kronika 17:5
2 Chronicles 17:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
2 Chronicles 17:5 in English
2 Chronicles 17:5 · Berean Standard Bible
So the LORD established the kingdom in his hand, and all Judah brought him tribute, so that he had an abundance of riches and honor.
Context
3Olúwa sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali. 4Ṣùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Israẹli. 5Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 6Ọkàn rẹ̀ sì gbé sókè si ọ̀nà Olúwa, pẹ̀lúpẹ̀lú, ó sì mú ibi gíga wọn àti ère òrìṣà Aṣerah kúrò ní Juda. 7Ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ Bene-Haili, Obadiah, Sekariah, Netaneli, Mikaiah láti máa kọ́ ni nínú ìlú Juda.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.