2 Kronika 17:3
2 Chronicles 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali.
2 Chronicles 17:3 in English
2 Chronicles 17:3 · Berean Standard Bible
Now the LORD was with Jehoshaphat because he walked in the earlier ways * of his father David. He did not seek out the Baals,
Context
1Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀ ó sì mú ara rẹ̀ lágbára sí lórí Israẹli. 2Ó sì fi ogun sínú gbogbo ìlú olódi Juda ó sì kó ẹgbẹ́ ológun ní Juda àti nínú ìlú Efraimu tí Asa baba rẹ̀ ti gbà. 3Olúwa sì wà pẹ̀lú Jehoṣafati nítorí, ní ọdún àkọ́kọ́ rẹ̀, ó rìn ní ọ̀nà ti baba rẹ̀ Dafidi ti rìn, kò sì fi ọ̀ràn lọ Baali. 4Ṣùgbọ́n ó wá Ọlọ́run baba rẹ̀ kiri ó sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀ ju iṣẹ́ Israẹli. 5Olúwa sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Juda sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehoṣafati, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.