Native Bible

2 Chronicles 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.

2 Chronicles 16:7 in English

2 Chronicles 16:7 · Berean Standard Bible

At that time Hanani the seer came to King Asa of Judah and told him, “Because you have relied on the king of Aram and not on the LORD your God, the army of the king of Aram has escaped from your hand.

Context

5Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. 6Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa. 7Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. 8Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. 9Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.