Native Bible

2 Chronicles 13:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Olúwa jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run.

2 Chronicles 13:9 in English

2 Chronicles 13:9 · Berean Standard Bible

But did you not drive out the priests of the LORD, the sons of Aaron, and the Levites? And did you not make priests for yourselves as do the peoples of other lands? Now whoever comes to consecrate himself with a young bull and seven rams can become a priest of things that are not gods.

Context

7Àwọn ènìyàn lásán sì kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹni búburú, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Rehoboamu ọmọ Solomoni ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fúnra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n. 8“Nísinsin yìí, ìwọ ṣètò láti kọ́ ìjọba Olúwa, tí ó wà lọ́wọ́ àwọn àtẹ̀lé Dafidi. Ìwọ jẹ́ ọmọ-ogun tí ó gbilẹ̀, ìwọ sì ní pẹ̀lú rẹ ẹgbọrọ màlúù wúrà ti Jeroboamu dà láti fi ṣe Ọlọ́run yín. 9Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Olúwa jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run. 10“Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. 11Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.