Native Bible

2 Chronicles 13:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

2 Chronicles 13:11 in English

2 Chronicles 13:11 · Berean Standard Bible

Every morning and every evening they present burnt offerings and fragrant incense to the LORD. They set out the rows of showbread on the ceremonially clean table, and every evening they light the lamps of the gold lampstand. We are carrying out the requirements of the LORD our God, while you have forsaken Him.

Context

9Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Olúwa jáde, àwọn ọmọ Aaroni àti àwọn ará Lefi. Tí ó sì ṣe àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run. 10“Ní ti àwa, Olúwa ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfáà tí ó ń sin Olúwa jẹ́ àwọn ọmọ Aaroni àwọn ará Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. 11Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ẹbọ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú Olúwa. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 12Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò fọn ìpè ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Israẹli, ẹ má ṣe dojú ìjà kọ Olúwa Ọlọ́run baba yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.” 13Nísinsin yìí, Jeroboamu ti rán àwọn ọ̀wọ́ ogun lọ yíká láti jagun ẹ̀yìn. Kí ó lè jẹ́ pé, tí òun bá wà níwájú Juda, bíba ní bùba á wà ní ẹ̀yìn wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.