2 Kronika 10:2
2 Chronicles 10:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti.
2 Chronicles 10:2 in English
2 Chronicles 10:2 · Berean Standard Bible
When Jeroboam son of Nebat heard about this, he returned from Egypt, where he had fled from King Solomon.
Context
1Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu nítorí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba. 2Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti. 3Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránṣẹ́ sí Jeroboamu àti òun àti gbogbo àwọn Israẹli lọ sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu wọ́n sì wí fún pé, 4“Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.