Native Bible

1 Timothy 5:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè.

1 Timothy 5:6 in English

1 Timothy 5:6 · Berean Standard Bible

But she who lives for pleasure is dead even while she is still alive.

Context

4Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run. 5Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru. 6Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè. 7Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn. 8Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.