1 Timotiu 4:14
1 Timothy 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
1 Timothy 4:14 in English
1 Timothy 4:14 · Berean Standard Bible
Do not neglect the gift that is in you, which was given you through the prophecy spoken over you at the laying on of the hands of the elders.
Context
12Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́. 13Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni. 14Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà. 15Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. 16Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.