1 Timotiu 4:12
1 Timothy 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.
1 Timothy 4:12 in English
1 Timothy 4:12 · Berean Standard Bible
Let no one despise your youth, but set an example for the believers in speech, in conduct, in love, in faith, in purity.
Context
10Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́. 11Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. 12Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́. 13Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni. 14Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.