Native Bible

1 Timothy 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́.

1 Timothy 3:14 in English

1 Timothy 3:14 · Berean Standard Bible

Although I hope to come to you soon, I am writing you these things

Context

12Kí àwọn díákónì jẹ́ ọkọ obìnrin kan, kí wọn káwọ́ àwọn ọmọ àti ilé ara wọn dáradára. 13Nítorí àwọn tí ó lo ipò díákónì dáradára ra ipò rere fún ara wọn, àti ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Kristi Jesu. 14Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. 15Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. 16Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fihàn nínú ara, tí a dá láre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn angẹli rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.