Native Bible

1 Timothy 1:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.

1 Timothy 1:15 in English

1 Timothy 1:15 · Berean Standard Bible

This is a trustworthy saying, worthy of full acceptance: Christ Jesus came into the world to save sinners, of whom I am the worst.

Context

13Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn, ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́. 14Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kristi Jesu. 15Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ. 16Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn. 17Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.