1 Tẹsalonika 5:4
1 Thessalonians 5:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè.
1 Thessalonians 5:4 in English
1 Thessalonians 5:4 · Berean Standard Bible
But you, brothers, are not in the darkness so that this day should overtake you like a thief.
Context
2nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wá bí olè lóru. 3Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àlàáfíà àti ààbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí ni rí ibi ààbò láti sá sí. 4Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè. 5Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́. 6Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.