1 Tẹsalonika 5:10
1 Thessalonians 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.
1 Thessalonians 5:10 in English
1 Thessalonians 5:10 · Berean Standard Bible
He died for us so that, whether we are awake or asleep, we may live together with Him.
Context
8Ṣùgbọ́n àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí ìgbàyà ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí àṣíborí. 9Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jesu Kristi. 10Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 11Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe. 12Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.