Native Bible

1 Samuel 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn.

1 Samuel 9:4 in English

1 Samuel 9:4 · Berean Standard Bible

So Saul passed through the hill country of Ephraim and then through the land of Shalishah, but did not find the donkeys. He and the servant went through the region of Shaalim, but they were not there. Then they went through the land of Benjamin, and still they did not find them.

Context

2Ó ní ọmọkùnrin kan tí à ń pè ní Saulu, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó yanjú, tí ó jẹ́ arẹwà, tí kò sí ẹni tó ní ẹwà jù ú lọ láàrín gbogbo àwọn ọmọ Israẹli—láti èjìká rẹ̀ lọ sí òkè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn tókù lọ. 3Nísinsin yìí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó jẹ́ ti Kiṣi baba Saulu sì sọnù. Nígbà náà, Kiṣi sọ fún Saulu ọmọ rẹ̀ pé, “Mú ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pẹ̀lú rẹ kí ẹ lọ láti wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” 4Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrín àwọn ìlú olókè Efraimu, ó sì kọjá ní àyíká ilẹ̀ Ṣaliṣa, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Ṣaalimu, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Benjamini, wọn kò sì rí wọn. 5Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.” 6Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ síbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a yóò gbà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.