Native Bible

1 Samuel 9:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”

1 Samuel 9:16 in English

1 Samuel 9:16 · Berean Standard Bible

“At this time tomorrow I will send you a man from the land of Benjamin, and you are to anoint him leader over My people Israel; he will save them from the hand of the Philistines. For I have looked upon My people, because their cry has come to Me.”

Context

14Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà. 15Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé, 16“Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.” 17Nígbà tí Samuẹli fojúrí Saulu, Olúwa sọ fún un pé, “Èyí ni ọkùnrin tí mo sọ fún ọ nípa rẹ̀, yóò darí àwọn ènìyàn mi.” 18Saulu sì súnmọ́ Samuẹli ní ẹnu-ọ̀nà ìlú, ó sì wí pé, “Sọ fún mi èmi ń bẹ̀ ọ́ níbo ni ilé wòlíì náà wà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.