1 Samuẹli 9:14
1 Samuel 9:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà.
1 Samuel 9:14 in English
1 Samuel 9:14 · Berean Standard Bible
So Saul and his servant went up toward the city, and as they were entering it, there was Samuel coming toward them on his way up to the high place.
Context
12“Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsin yìí, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga. 13Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbọdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsin yìí, ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.” 14Wọ́n gòkè lọ sí ìlú náà, bí wọ́n ti ń wọlé, níbẹ̀ ni Samuẹli, ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn bí ó ti ń lọ ibi gíga náà. 15Olúwa ti sọ létí Samuẹli ní ọjọ́ kan kí Saulu ó tó dé pé, 16“Ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò ran ọmọkùnrin kan sí ọ láti ilẹ̀ Benjamini. Fi òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ọmọ Israẹli, yóò gba àwọn ènìyàn mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini. Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn mi, nítorí igbe wọn ti dé ọ̀dọ̀ mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.