1 Samuẹli 7:9
1 Samuel 7:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn.
1 Samuel 7:9 in English
1 Samuel 7:9 · Berean Standard Bible
Then Samuel took a suckling lamb and offered it as a whole burnt offering to the LORD. He cried out to the LORD on behalf of Israel, and the LORD answered him.
Context
7Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. 8Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” 9Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn. 10Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.