1 Samuẹli 6:13
1 Samuel 6:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀.
1 Samuel 6:13 in English
1 Samuel 6:13 · Berean Standard Bible
Now the people of Beth-shemesh were harvesting wheat in the valley, and when they looked up and saw the ark, they were overjoyed at the sight.
Context
11Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán ààrùn oníkókó wà níbẹ̀. 12Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Beti-Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Filistini tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Beti-Ṣemeṣi. 13Nísinsin yìí, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀. 14Kẹ̀kẹ́ ẹrù wá sí pápá Joṣua ti Beti-Ṣemeṣi, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 15Àwọn ará Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.