Native Bible

1 Samuel 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán ààrùn oníkókó wà níbẹ̀.

1 Samuel 6:11 in English

1 Samuel 6:11 · Berean Standard Bible

Then they put the ark of the LORD on the cart, along with the chest containing the gold rats and the images of the tumors.

Context

9ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọlù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni.” 10Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dè é ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé. 11Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán ààrùn oníkókó wà níbẹ̀. 12Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Beti-Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Filistini tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Beti-Ṣemeṣi. 13Nísinsin yìí, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.