1 Samuẹli 6:1
1 Samuel 6:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Filistini fún oṣù méje,
1 Samuel 6:1 in English
1 Samuel 6:1 · Berean Standard Bible
When the ark of the LORD had been in the land of the Philistines seven months,
Context
1Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Filistini fún oṣù méje, 2àwọn ará Filistini pe àwọn àlùfáà, àti àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí ààyè rẹ̀.” 3Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.