1 Samuẹli 5:2
1 Samuel 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni.
1 Samuel 5:2 in English
1 Samuel 5:2 · Berean Standard Bible
carried it into the temple of Dagon, and set it beside his statue.*
Context
1Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu. 2Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni. 3Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. 4Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.