Native Bible

1 Samuel 4:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì.

1 Samuel 4:5 in English

1 Samuel 4:5 · Berean Standard Bible

When the ark of the covenant of the LORD entered the camp, all the Israelites raised such a great shout that it shook the ground.

Context

3Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” 4Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. 5Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì. 6Ní ìgbà tí àwọn Filistini gbọ́ ariwo náà wọ́n béèrè pé, “Kí ni gbogbo ariwo yìí ní ibùdó Heberu?” Nígbà tí wọ́n mọ̀ wí pé àpótí ẹ̀rí Olúwa ti wá sí ibùdó, 7àwọn Filistini sì bẹ̀rù pé, Ọlọ́run kékeré ti wọ ibùdó, wọ́n wí pé, “A wọ wàhálà, irú èyí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.