Native Bible

1 Samuel 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

1 Samuel 4:3 in English

1 Samuel 4:3 · Berean Standard Bible

When the troops returned to the camp, the elders of Israel asked, “Why has the LORD brought defeat on us before the Philistines today? Let us bring the ark of the covenant of the LORD from Shiloh, so that it may go * with us to save us from the hand of our enemies.”

Context

1Ọ̀rọ̀ Samuẹli tọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli wá. 2(1) Nísinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli jáde láti lọ bá àwọn Filistini jà. Àwọn ọmọ Israẹli sì pàgọ́ sí Ebeneseri àti àwọn Filistini ní Afeki. (2) Àwọn Filistini mú ogun wọn sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Israẹli, nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀, àwọn Filistini ṣẹ́gun Israẹli wọ́n pa ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin nínú ogun náà. 3Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun náà padà sí ibùdó, àwọn àgbàgbà Israẹli sì béèrè pé, “Èéṣe ti Olúwa fi mú kí àwọn Filistini ṣẹ́gun wa lónìí? Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa láti Ṣilo wá, kí ó ba à le lọ pẹ̀lú wa kí ó sì gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.” 4Nítorí náà a rán àwọn ènìyàn lọ sí Ṣilo, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá, ẹni tí ń wà láàrín àwọn Kérúbù àti àwọn ọmọ Eli méjèèjì Hofini àti Finehasi wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run. 5Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì dìde láti kígbe tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ sì mì tìtì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.