Native Bible

1 Samuel 4:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.

1 Samuel 4:20 in English

1 Samuel 4:20 · Berean Standard Bible

As she was dying, the women attending to her said, “Do not be afraid, for you have given birth to a son!” But she did not respond or pay any heed.

Context

18Nígbà tí ó dárúkọ àpótí ẹ̀rí Olúwa, Eli sì ṣubú sẹ́yìn kúrò lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ bodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí tí ó jẹ́ arúgbó ọkùnrin, ó sì tóbi, ó ti darí àwọn Israẹli fún ogójì ọdún. 19Aya ọmọ rẹ̀, ìyàwó Finehasi, ó lóyún ó súnmọ́ àkókò àti bí. Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn náà wí pé wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Olúwa lọ àti wí pé baba ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó rọbí ó sì bímọ, ó sì borí ìrora ìrọbí náà. 20Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i. 21Ó sì pe ọmọ náà ní Ikabodu, wí pé, “Kò sí ògo fún Israẹli mọ́,” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀. 22Ó si wí pé, “Ògo kò sí fún Israẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.