1 Samuẹli 31:4
1 Samuel 31:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Saulu mú idà, ó sì ṣubú lù ú.
1 Samuel 31:4 in English
1 Samuel 31:4 · Berean Standard Bible
Then Saul said to his armor-bearer, “Draw your sword and run it through me, or these uncircumcised men will come and run me through and torture me!” But his armor-bearer was terrified and refused to do it. So Saul took his own sword and fell on it.
Context
2Àwọn Filistini sì ń lépa Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Filistini sì pa Jonatani àti Abinadabu, àti Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu. 3Ìjà náà sì burú fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà. 4Saulu sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.”
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Saulu mú idà, ó sì ṣubú lù ú. 5Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si rí i pé Saulu kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀. 6Saulu sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.