1 Samuẹli 30:15
1 Samuel 30:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?” Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.”
1 Samuel 30:15 in English
1 Samuel 30:15 · Berean Standard Bible
“Will you lead me to these raiders?” David asked. And the man replied, “Swear to me by God that you will not kill me or deliver me into the hand of my master, and I will lead you to them.”
Context
13Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ọmọ ta ni ìwọ? Àti níbo ni ìwọ ti wá?”
Òun sì wí pé, “Ọmọ ará Ejibiti ni èmi, ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ará Amaleki. Olúwa mi fi mí sílẹ̀, nítorí pé láti ọjọ́ mẹ́ta ni èmi ti ṣe àìsàn. 14Àwa sì gbé ogun lọ sí ìhà gúúsù tí ará Kereti, àti sí ìhà ti Juda, àti sí ìhà gúúsù ti Kalebu; àwa sì kun Siklagi ní iná.” 15Dafidi sì bi í léèrè pé, “Ìwọ lè mú mí sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun yìí lọ bí?”
Òun sì wí pé, “Fi Ọlọ́run búra fún mi pé, ìwọ kì yóò pa mí, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò sì fi mi lé olúwa mi lọ́wọ́; èmi yóò sì mú ọ sọ̀kalẹ̀ tọ ẹgbẹ́ ogun náà lọ.” 16Ó sì mú un sọ̀kalẹ̀, sì wò ó, wọ́n sì tàn ká ilẹ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ìkógun púpọ̀ tí wọ́n kó láti ilẹ̀ àwọn Filistini wá, àti láti ilẹ̀ Juda. 17Dafidi sì pa wọ́n láti àfẹ̀mọ́júmọ́ títí ó fi di àṣálẹ́ ọjọ́ kejì: kò sí ẹnìkan tí ó là nínú wọn, bí kọ̀ ṣe irinwó (400) ọmọkùnrin tí wọ́n gun ìbákasẹ tí wọ́n sì sá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.