1 Samuẹli 30:10
1 Samuel 30:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Dafidi àti irinwó (400) ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn.
1 Samuel 30:10 in English
1 Samuel 30:10 · Berean Standard Bible
because two hundred men were too exhausted to cross the brook. But David and four hundred men continued in pursuit.
Context
8Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa wí pé, “Kí èmi ó lépa ogun yìí bi? Èmi lè bá wọn?”
Ó sì dá a lóhùn pé, “Lépa, nítorí pé ni bíbá ìwọ yóò bá wọn, ni gbígbà ìwọ yóò sì rí wọn gbà.” 9Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti ẹgbẹ̀ta (600) ọmọkùnrin tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì wá sí ibi àfonífojì Besori, apá kan sì dúró. 10Ṣùgbọ́n Dafidi àti irinwó (400) ọmọkùnrin lépa wọn: igba ènìyàn tí àárẹ̀ mú, tiwọn kò lè kọjá odò Besori sì dúró lẹ́yìn. 11Wọ́n sì rí ará Ejibiti kan ní oko, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ, ó sì jẹ; wọ́n sì fún un ní omi mu. 12Wọ́n sì fún un ní àkàrà, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti síírí àjàrà gbígbẹ́ méjì: nígbà tí ó sì jẹ ẹ́ tán, ẹ̀mí rẹ̀ sì sọjí: nítorí pé kò jẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi ní ọjọ́ mẹ́ta ní ọ̀sán, àti ní òru.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.