Native Bible

1 Samuel 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun.

1 Samuel 3:13 in English

1 Samuel 3:13 · Berean Standard Bible

I told him that I would judge his house forever for the iniquity of which he knows, because his sons blasphemed God * and he did not restrain them.

Context

11Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Wò ó, èmi ṣetán láti ṣe ohun kan ní Israẹli tí yóò jẹ́ kí etí gbogbo ènìyàn tí ó gbọ́ ọ já gooro. 12Ní ìgbà náà ni èmi yóò mú ohun gbogbo tí mo ti sọ sí ilé Eli ṣẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. 13Nítorí èmi sọ fún un pé, Èmi yóò ṣe ìdájọ́ fún ilé rẹ̀ títí láé nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí òun mọ̀ nípa rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀-òdì, òun kò sì dá wọn lẹ́kun. 14Nítorí náà, mo búra sí ilé Eli, ‘Ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ilé Eli ni a kì yóò fi ẹbọ tàbí ọrẹ mú kúrò láéláé.’ ” 15Samuẹli dùbúlẹ̀ títí di òwúrọ̀ nígbà náà ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, ó sì bẹ̀rù láti sọ ìran náà fún Eli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.