Native Bible

1 Samuel 26:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa.

1 Samuel 26:23 in English

1 Samuel 26:23 · Berean Standard Bible

May the LORD repay every man for his righteousness and faithfulness. For the LORD delivered you into my hand today, but I would not stretch out my hand against the LORD’s anointed.

Context

21Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.” 22Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á. 23Kí Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa. 24Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.” 25Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dafidi ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.” Dafidi sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Saulu sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.