1 Samuẹli 25:21
1 Samuel 25:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyí tí i ṣe ti eléyìí ní aginjù, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni ó sì fi ibi san ìre fún mi yìí.
1 Samuel 25:21 in English
1 Samuel 25:21 · Berean Standard Bible
Now David had just finished saying, “In vain I have protected all that belonged to this man in the wilderness. Nothing that belongs to him has gone missing, yet he has paid me back evil for good.
Context
19Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Máa lọ níwájú mi; wò ó, èmi ń bọ̀ lẹ́yìn yín,” ṣùgbọ́n òun kò wí fún Nabali baálé rẹ̀. 20Bí o ti gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó sì ń sọ̀kalẹ̀ sí ibi ìkọ̀kọ̀ òkè náà, wò ó, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ níwájú rẹ̀; òun sì wá pàdé wọn. 21Dafidi sì ti wí pé, “Ǹjẹ́ lásán ni èmi ti pa gbogbo èyí tí i ṣe ti eléyìí ní aginjù, ti ohunkóhun kò sì nù nínú gbogbo èyí ti í ṣe tirẹ̀: òun ni ó sì fi ibi san ìre fún mi yìí. 22Bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni ki Ọlọ́run ó ṣe sí àwọn ọ̀tá Dafidi, bi èmi bá fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú gbogbo èyí tí i ṣe tirẹ̀ títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀.” 23Abigaili sì rí Dafidi, ó sì yára, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì dojúbolẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.