1 Samuẹli 25:12
1 Samuel 25:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
1 Samuel 25:12 in English
1 Samuel 25:12 · Berean Standard Bible
So David’s men turned around and went back, and they relayed to him all these words.
Context
10Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀. 11Ǹjẹ́ ki èmi o mú oúnjẹ mi, àti omi mi, àti ẹran mi ti mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, ki èmi sì fi fún àwọn ọkùnrin ti èmi kò mọ̀ ibi wọ́n ti wá?” 12Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì padà, wọ́n sì wá, wọn si rò fún un gẹ́gẹ́ bi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 13Dafidi sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idà rẹ́ mọ́ ìdí,” olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ̀ mọ́ ìdí; àti Dafidi pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó (400) ọmọkùnrin si gòkè tọ Dafidi lẹ́yìn; igba si jókòó níbi ẹrù. 14Ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin Nabali si wí fún Abigaili aya rẹ̀ pé, “Wo o, Dafidi rán oníṣẹ́ láti aginjù wá láti kí olúwa wa; ó sì kanra mọ́ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.