Native Bible

1 Samuel 24:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.

1 Samuel 24:13 in English

1 Samuel 24:13 · Berean Standard Bible

As the old proverb says, ‘Wickedness proceeds from the wicked.’ But my hand will never be against you.

Context

11Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. 12Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 13Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 14“Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15Kí Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.