1 Samuẹli 23:2
1 Samuel 23:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”
1 Samuel 23:2 in English
1 Samuel 23:2 · Berean Standard Bible
So David inquired of the LORD, “Should I go and attack these Philistines?” And the LORD said to David, “Go and attack the Philistines and save Keilah.”
Context
1Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” 2Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?”
Olúwa sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.” 3Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?” 4Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ Olúwa. Olúwa sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.