Native Bible

1 Samuel 23:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.

1 Samuel 23:14 in English

1 Samuel 23:14 · Berean Standard Bible

And David stayed in the wilderness strongholds and in the hill country of the Wilderness of Ziph. Day after day Saul searched for him, but God would not deliver David into his hand.

Context

12Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.” 13Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta (600) ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.” 14Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sá pamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́. 15Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. 16Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.