Native Bible

1 Samuel 21:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!”

1 Samuel 21:5 in English

1 Samuel 21:5 · Berean Standard Bible

David answered, “Women have indeed been kept from us, as is usual when I set out. And the equipment of the young men is holy, as it is even on common missions, and all the more at this time.”

Context

3Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.” 4Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́. Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!” 5Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!” 6Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò. 7Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dádúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Doegi, ará Edomu olórí nínú àwọn darandaran Saulu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.