1 Samuẹli 17:55
1 Samuel 17:55 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”
1 Samuel 17:55 in English
1 Samuel 17:55 · Berean Standard Bible
As Saul had watched David going out to confront the Philistine, he said to Abner the commander of the army, “Abner, whose son is this young man?” “As surely as you live, O king,” Abner replied, “I do not know.”
Context
53Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli sì padà láti máa lé àwọn ará Filistini, wọ́n sì ba ibùdó wọn jẹ́. 54Dafidi gé orí Filistini ó sì gbé e wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ohun ìjà Filistini sínú àgọ́ tirẹ̀. 55Bí Saulu sì ti wo Dafidi bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Filistini, ó wí fún Abneri, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Abneri, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?”
Abneri dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.” 56Ọba sì wí pé, “Wádìí ọmọ ẹni tí ọmọdékùnrin náà ń ṣe.” 57Kété tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ pa Filistini, Abneri sì mú u wá síwájú Saulu, orí Filistini sì wà ní ọwọ́ Dafidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.