1 Samuẹli 15:22
1 Samuel 15:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.
1 Samuel 15:22 in English
1 Samuel 15:22 · Berean Standard Bible
But Samuel declared: “Does the LORD delight in burnt offerings and sacrifices as much as in obedience to His voice? Behold, obedience is better than sacrifice, and attentiveness is better than the fat of rams.
Context
20Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí Olúwa rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. 21Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún Olúwa láti fi rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.” 22Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé,
“Olúwa ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ
ju kí a gba ohùn Olúwa gbọ́?
Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ,
ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. 23Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,
àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.
Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,
Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.” 24Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.