Native Bible

1 Samuel 14:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan.

1 Samuel 14:39 in English

1 Samuel 14:39 · Berean Standard Bible

As surely as the LORD who saves Israel lives, even if it is my son Jonathan, he must die!” But not one of the troops said a word.

Context

37Nígbà náà ni Saulu béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé, “Ṣé kí n sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn Filistini lọ bí? Ǹjẹ́ ìwọ yóò fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́ bí?” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà. 38Saulu sì wí pé, “Ẹ wá síyìn-ín ín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olórí ogun, kí a ṣe ìwádìí irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ ti ṣẹ̀ lónìí. 39Bí Olúwa tí ó gba Israẹli là ti wà, bí ó bá ṣe pé a rí í lára Jonatani ọmọ mi, ó ní láti kú.” Ṣùgbọ́n ẹnìkankan nínú wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kan. 40Nígbà náà ni Saulu wí fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ lọ sí apá kan; èmi àti Jonatani ọmọ mi yóò lọ sí apá kan.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú rẹ.” 41Nígbà náà ni Saulu gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli pé, “Fún mi ní ìdáhùn tí ó tọ́.” A sì mú Jonatani àti Saulu nípa ìbò dídì, àwọn ènìyàn náà sì yege.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.