1 Samuẹli 14:24
1 Samuel 14:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.
1 Samuel 14:24 in English
1 Samuel 14:24 · Berean Standard Bible
Now the men of Israel were in distress that day, for Saul had placed the troops under an oath, saying, “Cursed is the man who eats any food before evening, before I have taken vengeance on my enemies.” So none of the troops tasted any food.
Context
22Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná. 23Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni. 24Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ. 25Gbogbo àwọn ènìyàn sì wọ inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀ náà. 26Nígbà tí wọ́n dé inú igbó náà, wọ́n sì rí oyin ń sun jáde, kò sí ẹni tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan ẹnu rẹ̀ síbẹ̀, nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìfiré.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.