1 Samuẹli 14:22
1 Samuel 14:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná.
1 Samuel 14:22 in English
1 Samuel 14:22 · Berean Standard Bible
When all the Israelites who had been hiding in the hill country of Ephraim heard that the Philistines were fleeing, they also joined Saul and Jonathan in the battle.
Context
20Saulu àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ sì péjọ, wọ́n sì lọ sí ojú ìjà. Wọ́n sì bá gbogbo àwọn Filistini ní ìdàrúdàpọ̀ ńlá, idà olúkúlùkù sì wà lára ọmọ ẹnìkejì rẹ̀. 21Àwọn Heberu tí ó ti wà lọ́dọ̀ àwọn Filistini tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti gòkè tẹ̀lé wọn lọ sí àgọ́ wọn wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani. 22Nígbà tí gbogbo àwọn Israẹli tí ó ti pa ara wọn mọ́ nínú òkè ńlá Efraimu gbọ́ pé àwọn Filistini sá, wọ́n darapọ̀ mọ́ ìjà náà ní ìlépa gbígbóná. 23Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì gba Israẹli ní ọjọ́ náà, ìjà náà sì rékọjá sí Beti-Afeni. 24Gbogbo ọkùnrin Israẹli sì wà ní ìpọ́njú ńlá ní ọjọ́ náà, nítorí pé Saulu ti fi àwọn ènìyàn gégùn ún wí pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ó jẹ oúnjẹ títí di alẹ́, títí èmi yóò fi gbẹ̀san mi lára àwọn ọ̀tá mi!” Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkankan nínú ọ̀wọ́ ogun náà tí ó fi ẹnu kan oúnjẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.