Native Bible

1 Samuel 12:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”

1 Samuel 12:3 in English

1 Samuel 12:3 · Berean Standard Bible

Here I am. Bear witness against me before the LORD and before His anointed: Whose ox or donkey have I taken? Whom have I cheated or oppressed? From whose hand have I accepted a bribe and closed my eyes? Tell me, and I will restore it * to you.”

Context

1Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín. 2Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí. 3Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.” 4Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.” 5Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.