Native Bible

1 Samuel 12:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”

1 Samuel 12:17 in English

1 Samuel 12:17 · Berean Standard Bible

Is it not the wheat harvest today? I will call on the LORD to send thunder and rain, so that you will know and see what a great evil you have committed in the sight of the LORD by asking for a king.”

Context

15ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín. 16“Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! 17Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.” 18Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀. 19Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.