Native Bible

1 Samuel 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’

1 Samuel 10:18 in English

1 Samuel 10:18 · Berean Standard Bible

and said to the Israelites, “This is what the LORD, the God of Israel, says: ‘I brought Israel up out of Egypt, and I rescued you from the hands of the Egyptians and of all the kingdoms that oppressed you.’

Context

16Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ. 17Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’ 19Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti kọ Ọlọ́run yín, tí ó gbà yín kúrò nínú gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú yín. Ẹ̀yin sì ti sọ pé, ‘Rárá, yan ọba kan fún wa.’ Báyìí, ẹ kó ara yín jọ níwájú Olúwa ní ẹ̀yà àti ìdílé yín.” 20Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.