1 Samuẹli 10:16
1 Samuel 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ.
1 Samuel 10:16 in English
1 Samuel 10:16 · Berean Standard Bible
And Saul replied, “He assured us that the donkeys had been found.” But Saul did not tell his uncle what Samuel had said about the kingship.
Context
14Nísinsin yìí, arákùnrin baba Saulu béèrè lọ́wọ́ Saulu àti ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni ẹ lọ?”
Ó wí pé, “À ń wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,” ṣùgbọ́n nígbà tí a kò rí wọn, a lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli. 15Arákùnrin baba Saulu wí pé, “Sọ fún mi ohun tí Samuẹli wí fún un yín.” 16Saulu dáhùn pé, “Ó fi dá wa lójú pé wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣùgbọ́n kò sọ fún arákùnrin baba a rẹ̀ ohun tí Samuẹli sọ nípa ọba jíjẹ. 17Samuẹli pé àwọn ọmọ Israẹli jọ sí iwájú Olúwa ní Mispa. 18Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Èmi mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti, Èmi sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ agbára Ejibiti àti gbogbo ìjọba tí ó ń pọ́n ọn yín lójú.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.