Native Bible

1 Samuel 1:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni.

1 Samuel 1:15 in English

1 Samuel 1:15 · Berean Standard Bible

“No, my lord,” Hannah replied. “I am a woman oppressed in spirit. I have not had any wine or strong drink, but I have poured out my soul before the LORD.

Context

13Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó. 14Eli sì wí fún un pé, “Yóò ti pẹ́ fún ọ tó tí ìwọ yóò máa yó? Mú ọtí wáìnì rẹ̀ kúrò.” 15Hana dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa mi, èmi ni obìnrin oníròbìnújẹ́. Èmi kò mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle; èmi ń tú ọkàn mi jáde sí Olúwa ni. 16Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí obìnrin búburú. Èmi ti ń gbàdúrà níhìn-ín nínú ìrora ọkàn àti ìbànújẹ́ mi.” 17Eli dáhùn pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Israẹli fi ohun tí ìwọ ti béèrè ní ọwọ́ rẹ̀ fún ọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.