1 Samuẹli 1:11
1 Samuel 1:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.”
1 Samuel 1:11 in English
1 Samuel 1:11 · Berean Standard Bible
And she made a vow, pleading, “O LORD of Hosts, if only You will look upon the affliction of Your maidservant and remember me, not forgetting Your maidservant but giving her a son, then I will dedicate him to the LORD all the days of his life, and no razor shall ever come over his head.”
Context
9Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n tún mu tán ní Ṣilo, Hana dìde wá síwájú Olúwa. Nígbà náà, Eli àlùfáà wà lórí àga ní ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ní ibi tí ó máa ń jókòó. 10Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn Hana sọkún gidigidi, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 11Ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, jùlọ tí ìwọ bá le bojú wo ìránṣẹ́bìnrin rẹ kí ìwọ sì rántí rẹ̀, tí ìwọ kò sì gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ yóò fún un ní ọmọkùnrin, nígbà náà èmi yóò sì fi fún Olúwa ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ a kì yóò sì fi abẹ kàn án ní orí.” 12Bí ó sì ṣe ń gbàdúrà sí Olúwa, Eli sì kíyèsi ẹnu rẹ̀. 13Hana ń gbàdúrà láti inú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ètè rẹ̀ ni ó ń mì, a kò gbọ́ ohùn rẹ̀. Eli rò wí pé ó ti mu ọtí yó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.